Ẹ̀yin agbébọn, Iru Ekun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láwọn igbó tó wà lẹ́kùn Gúúṣù Kwara, ẹ tètè para mọ́, gbogbo ìlẹ̀ Ìgbómìnà ni máà dé - Sunday Igboho

Ẹsẹ o gbero loni nibi ifilọlẹ ikọ eleto àbò Iru Ẹkun ni ipinlẹ Kwara gẹgẹ bi ara igbesẹ lati mu ki eto aabo duro re ni ẹkun Guusu Kwara.
Ajafun Iran Yorùbá nni, Oloye Sunday Igboho lo sefilọlẹ ikọ eleto aabo naa lọjọbọ ana ni ile ọmọ ibilẹ Igbomina to wa ni ilu Ganmọ, Ilọrin, Ipinlẹ Kwara.
BBC News Yoruba bawọn peju sibi eto naa to bẹrẹ ni nnkan bi ago meji abọ Ọsan, tawọn eeyan ẹkun Gusu Kwara si peju si lọpọ yanturu.
Nigba to n sọrọ, Oloye Sunday Igboho sọ pe, asiko ti to bayii ti alafia yóò jọba ni Ẹkun Guusu Kwara.
Oloye Sunday Igboho salaye pe, Aarẹ Bọla Tinubu ti fun oun lasẹ lati bẹrẹ ikọ eleto alaabo Iru Ẹkun pẹlu ifọwọsowọpọ awọn Ọlọpaa.

"Ẹ̀yin ọdaran, ẹ tete kuro ninu Igbo Ẹkun Gusu Kwara nitori Iru Ẹkun ti bẹrẹ iṣẹ ni Kwara"
Oloye Sunday Igboho fikun pe, gbogbo ilu tawọn agbesunmọmi ti le awọn eeyan kuro nilu ni Ẹkun Gusu Kwara loun yóò de bẹrẹ lati oni lọ.
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, ẹnikẹni ti awọn ba ba ibọn lọwọ rẹ ninu Igbo lai se ọdẹ tabi vigilante, ọdaran ni.
O ni kawọn oniwa ọdaran tete kuro ninu Igbo Ẹkun Gusu Kwara nitori Iru Ẹkun ti bẹrẹ iṣẹ ni Kwara.
O tẹsiwaju pe, aarẹ Bola Tinubu ni ki wọn maa gboriyin fun lori aseyọri iru ẹkun, eni yoowu to ba ni ifẹ si iṣẹ Iru Ẹkun ko forukọsilẹ, ọfẹ ni igbaniwọle.
Igboho wa gba awọn ọmọ ikọ iru Ẹkun ni mọran lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro pẹlu alaye pe, ki wọn yago fun sise idajọ lọwọ ara ẹni.
O tun lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Tinubu ati Gomina Abdulrahman Abdulrazak fun aye ti wọn fi gbàá.
Lati bi ọdun melo kan sẹyin ni awọn eeyan ẹkun Gusu Kwara ko ti gbadun mọ nitori ikọlu awọn ajinigbe - Alaga ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Igbomina lapapọ
Ninu ọrọ rẹ, Alaga ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Igbomina lapapọ Oloye Bisi Fakayọde sọ pe, inu awọn dun púpọ lati ri oloye Sunday Igboho lonii.
O salaye pe, ọpọ ipenija lẹkun Gusu Kwara n koju nidi eto abo pẹlu bi awọn ajinigbe ati awọn agbesunmọmi se n soro bi agbọn.
Oloye Bisi Fakayọde salaye pe, lati bi ọdun melo kan seyin ni awọn eeyan ẹkun Gusu Kwara o ti gbadun mọ latari awọn ajinigbe.
O tẹsiwaju pe, awọn eeyan ilẹ Igbomina ati Ekiti ipinlẹ Kwara ko le loko mọ ti gbogbo nnkan si le koko.
O salaye pe, laipẹ yii ni wọn sekupa agbẹ kan si inu oko ni Isanlu Isin, nijọba ibilẹ Isin Ipinlẹ Kwara.
Pẹlu afikun pe, ọmọ kan ti wọn ji gbe bawon ara-ile rẹ sọrọ ki wọn máse gbe owo wa, nitori bi wọn ba yọnda oun, oun o le jẹ eeyan mọ.
O ni gbogbo gba ni wọn n ba oun sun, ti ọmọ naa si pada ku.
O salaye pe, ọrọ yii ti su awọn lo jẹ ki awọn lọ ranṣẹ pe Sunday Igboho lati wa ran awọn lọwọ.
Ninu ọrọ tiẹ Oloye Ayọ Samuel, to soju awọn eeyan Ekiti Kwara sọ pe, losu keji ọdun 2024 lawọn agbesunmọmi yawọ ilu Koro, ti wọn si sekupa Ọba ilu naa.
O ni lẹyin naa ni wọn ji Olori Ọba gbe lọ ti ilu naa sí san millionu mẹrinla náírà ki wọn to yọnda Olori Ọba.
O wa fidi rẹ mulẹ pe, wọn pa eeyan mẹta si inu ile ijọsin ni ilu Eruku, ti wọn si ji eeyan metadinlogun gbe lọ.
Onimọ ẹrọ Basiru Lawal, to soju awọn eeyan Ibọlọ ni awọn bẹ Oloye Sunday Igboho lọwẹ lati ran awọn eeyan ẹkun Gusu Kwara lọwọ lori ọrọ eto abo.

Ki lo sẹlẹ tẹlẹ latẹyin wa nipa eto aabo ẹkun guusu Kwara?
Ẹkun Gusu Kwara n koju iṣoro ọrọ eto abo lati bi ọdun melo kan sẹyin.
Iṣẹlẹ naa si ti ko ipaya ba ọpọ awọn ara ilu de bi pe ọpọ lo ti sa kuro nilu wọn, ti wọn si sa lọ si ilu mi.
Awọn ijọba ibilẹ ti ọrọ naa kan julọ ni Ijọba ibilẹ Ifẹlodun, Ekiti, Isin, Oke ẹrọ ati ijọba ibilẹ Irẹpodun ti gbogbo wọn wa ni Ẹkun Gusu Kwara.
Awọn agbesunmọmi wọ inu ilu lọ lati lọ ji awọn eeyan gbe, bẹẹni wọn tún ji awọn eeyan gbe nile Ijọsin.
Ko si Isọ oru lawọn ile ijọsin to wa lẹkun idibo naa mọ, ti bẹru ti bẹru lawọn eeyan n gbe lẹkun naa.
Awọn to ni ayẹyẹ o le lọ ilu abinibi wọn lati lọ ṣe ayẹyẹ mọ, se ni wọn sin oku iya tabi Baba wọn si ilu ti wọn gbe latari ibẹru awọn ajinigbe.
Koda, ijọba ti pasẹ laipe yii pe ko gbọdọ ṣi ayẹyẹ opin Ọdun tawọn ile ẹkọ ṣe lọdọọdun.
Igbesẹ wo ni ijọba gbe
Ijọba ipinlẹ Kwara naa ko kawọ gbera lori iṣẹlẹ naa.
Lọdun to kọja ni ijọba da ikọ eleto abo ọdẹ Asọgbo forest Gaurd silẹ ti wọn si n ṣiṣẹ lati koju iṣoro eto abo.
Lọsẹ yii naa tun ni Aarẹ Bọla Tinubu fọwọsi idasilẹ Olu Ile Iṣẹ Ajọ Ọmọ ogun ṣi ilu Omu-aran ni ijọba ibilẹ Irẹpodun Ipinlẹ Kwara.
Eyi o si sẹyin igbesẹ Gomina Ipinlẹ Kwara lati bẹbẹ fun iranlọwọ ijọba apapọ.



























