Mi ò lérò pé mo lè dé ipò Ìmáàmù ìlú Ilorin, àmọ́, mo ti máa ń rí àwọn àpẹẹrẹ kan tipẹ́ - Ìmáàmù Ilorin tuntun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Imaamu Agba tuntun ilu Ilorin, Muhammad Bashir Dasuki, ti sọ pe oun ko lero wi pe oun le jẹ Imaamu ilu Ilorin, amọ, o ni oun ti maa n ri awọn apẹẹrẹ kan tipẹ.

Imaamu Dasuki ni lọpọ igba lawọn eeyan maa n pe oun ni Aliman nibi kibi ti wọn ba ti ri oun.

''Lati igba yẹn ni mo ti maa n ranti ọmọ ẹni ti mo o ṣe, mo si maa n ṣọ iru awọn eeyan ti mo n baṣe pọ.

Ọpọ eeyan to maa n pe ni Imaamu ni ko mọ iru ile ti mo ti jade wi pe ile imaamu gbogbo ilu ni.

Ẹkọ ti mo kọ ni pe ko dara ki eeyan maa fi ara rẹ han ṣaaju asiko ti Ọlọrun maa fi ẹni naa han,'' Imaamu Dasuki lo sọ bẹẹ.

Imaamu Dasuki sọ fun BBC Yoruba wi pe ''lati ọdun 2004 ni mo ti maa n ṣe majir nigba ti awọn baba wa mejeeji ba pari eto tan.

IWọn fi ẹkọ ibọwọ fun aṣiwaju ati ibọwọ fun awọn agbalagba kọ wa lati ile.

Afojusun mi ni pe ki a fi ẹsin kọ ara wọn, ki onikaluku si wa ni iṣọkan, ka jẹ ki ogun o mi.''

Imaamu Ilorin tuntun fikun ọrọ rẹ pe awọn musulumi ko gbọdọ jẹ ki ero awọn ọta Islam to maa n sọ pe ẹsin jagidijagan ni ẹsin Islam ''ṣẹ mọ wa lara.

Ka ma jẹ ki ọrọ wọn ṣẹ lara wa wi pe awa musulumi o fẹran ara wa, ka tun a ma jẹ ki ọrọ ti wọn maa n sọ pe ẹsin awa musulumi ko ni ipilẹ tori ẹsin wa ni ipilẹ.''

O ni iṣẹ nla ni iṣẹ imaamu toun ṣẹṣẹ gba yii tori oun ni lati lọ si ibi ti oku ba ti ku bayii ati pe oun tun ni lati ṣe awọn eto mii.