Ọlọ́pàá mẹ́rin tó bèèrè owó ẹ̀yìn lọ́wọ́ awakọ̀ lọ́nà márosẹ̀ Ọrẹ si Benin wọ gàù, ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí wọn

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin fidio kan to n lọ lori ayelujara, nibi ti ikọ ọlọpaa kan ti huwa aitọ si awakọ adani ti wọn da duro lati yẹ iwe ọkọ rẹ wo, nipinlẹ Ondo, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti dide si iṣẹlẹ ọhun.

Gẹgẹ bi kọmandi ọlọpaa Ondo ṣe wi loju opo X ati nibi ipade awọn akọroyin ti wọn pe lori iṣẹlẹ yii, wọn ti mọ awọn ọlọpaa to wa ninu fidio yii, wọn ti fọwọ ofin mu wọn pẹlu, bẹẹ ni iwadii ati igbesẹ to yẹ si ti bẹrẹ lorii wọn.

Awọn ọlọpaa naa bi DSP Abayomi Jimoh, Alukoro ọlọpaa Ondo ṣe darukọ ati nọmba idanimọ wọn ni:

AP/No. 207454 ASP Elomore Sodayo, AP/No. 332012 Inspector Adefila Adewale, AP/No. 33244, Inspector Olorunfemi Opeyemi, ati AP/No. 332369 Inspector Odusola Peter.

Ki lo ṣẹlẹ pato?

Ninu fidio to wa loju opo ayelujara naa ni a ti ri awọn ọlọpaa nibudo kan ti wọn ti n yẹ iwe ọkọ wo loju ọna marosẹ Eko si Benin, nibẹ ni wọn ti da awakọ yii duro.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Keje ti iṣẹlẹ naa waye ni fidio naa gbode.

Ọlọpaa ọkunrin kan ni fidio naa fi han to n yẹ iwe ọkọ awakọ adani kan wo, to si ri i pe awọn iwe naa pe perepere.

Bo ṣe n yẹ iwe naa wo lo n beere ibeere lọwọ awakọ pe nibo lo ti wa, iyẹn si sọ fun un pe UK ni oun ti de sipinlẹ Ondo, ilu Akure ni oun si n gbe.

Bi ọlọpaa ṣe yẹ awọn iwe naa wo lo ni ki awakọ ṣe ohun to yẹ, bẹẹ ni ko da iwe aṣẹ ọkọ wiwa awakọ naa to ti gba lọwọ rẹ pada.

Awakọ sọ fun ọlọpaa pe ko mu iwe naa pada foun, amọ ọlọpaa yii ni niṣe loun ko ba tiẹ da a duro lọtọ to ba lọ jẹ pe ẹya Igbo ni.

O ni ki awakọ naa ṣe ẹtọ, eyi ti ko fi gbogbo ẹnu salaye ṣugbọn to ti ye awakọ, ti iyẹn ko si fẹ ṣe nigba ti iwe ọkọ rẹ pe.

Koda, nigba ti ara UK naa sọ fun un pe oun n ṣe fidio rẹ o, pe oun n ka ohun to n ṣelẹ sori foonu oun, agbofinro naa ko bikita, bẹẹ ni ko da iwe aṣẹ awakọ ọhun pada .

Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ni ọlọpaa keji kọju si ẹnikeji ara ilu oyinbo ti wọn jọ n lọ ki wọn to da wọn duro, o ni oun yoo gba a leti bi ko ba ṣọra, oun si le fi ọwọ ofin mu un pẹlu koun si ti i mọle.

Ṣaaju ni awakọ ti ko awọn iwe ọkọ atawọn iwe yoku to beere fun un, amọ ọlọpaa naa tun n mu ẹnu ba awọn iwe ẹrù to wa ninu ọkọ adani ti ọkunrin naa ko sinu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.

Ohun ti ọlọpaa Ondo ni awọn yoo ṣe lorii rẹ

Nigba to n ṣalaye iha ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo kọ si ọrọ yii, Alukoro wọn, DSP Abayomi Jimoh, ṣalaye pe kọmandi ọlọpaa ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ohun to ṣẹlẹ ninu fidio naa.

O ni ''kọmandi ọlọpaa ko fi aaye gba eyikeyi iwa aikọṣẹmọṣẹ latọdọ awọn oṣiṣẹ wa nigba ti wọn ba n ṣiṣẹ wọn lọwọ. Fun idi eyi, a ti bẹrẹ iwadii kikun lori iṣẹlẹ naa".

O ni ileeṣẹ agbofinro naa ko fi aaye gba iwa ta ni yoo mu mi ati ijẹgaba.

O fi kun un pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, CP Felix Ohagwu, ti paṣẹ iwadii to lọọrin lori iṣẹlẹ yii, kawọn si fi bi awọn agbofinro naa ṣe lọwọ ninu rẹ to han.

Kọmandi ọlọpaa Ondo fi da araalu loju, pe abọ iwadii naa yoo to wọn leti, akoyawọ ati ododo lawọn yoo si fi gbe e kalẹ.

Ṣaaju ni wọn ti rọ awọn ọlọpaa ti ọrọ naa kan lati waa jọwọ ara wọn kalẹ, ki wọn le ṣeranwọ ti yoo kun iwadii naa lọwọ, ti yoo si mu idajọ ododo waye.

Ọpọ eeyan lo ti n sọ ero ọkan wọn lori iwa ti awọn ọlọpaa naa wu, paapaa nipa adojusọ ẹya .

Ohun ti ọpọ eeyan n sọ lori ẹ ni pe iwa ẹlẹyamẹya ti ọlọpaa akọkọ naa wu ko fi Naijiria han bii orilẹede to duro niṣọkan ni