Tinubu àti Atiku tún gbéná wojú ara wọn lórí ìgbẹ́jọ́ Tinubu tí iléeṣẹ́ kan gbé dìde ní Amẹ́ríkà

Tinubu wọ aṣọ pẹlu fila olomi aro, o wọ igo oju o n wo ẹgbẹ, Atiku wọ aṣọ alawọdudu ati funfun, oun naa wọ igo oju, o n wo ẹgbẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Bola Tinubu/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ifanfa to n waye laaarin Aarẹ orilẹ ede Naijiria, Bola Tinubu ati oludije lẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Atiku Abubakar tun ti gba ọna mii yọ, ti igun mejeeji si n fi oniruuru ẹsun iwa ajẹbanu atawọn ẹsun nla mii kan ara wọn.

Awuyewuye to n waye lasiko yii laaarin awọn mejeeji ko ṣẹyin bi ileeṣẹ aarẹ ṣe fẹsun kan Atiku pe o n ṣe agbatẹru ileeṣẹ kan ni Amẹrika lati lọ ṣagbedide iwadii lori igbẹjọ ti Tinubu koju ni Amẹrika lọdun 1993.

Ileeṣẹ aarẹ fẹsun pe kan Atiku kii ṣed ọmọ Naijiria rere lo ṣe lọ kọwe ẹsun si ijọba Amẹrika lori iṣẹlẹ to ti le lọgbọn ọdun ati pe nitori erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria ati ọrọ oṣelu lo fi n huwa naa.

Agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga ninu atẹjade kan to fi lede sọ pe iwadii ti waye lori ẹsun naa ti wọn ko si ri ẹbi Tinubu tabi fiya kankan jẹ ẹ, to si sọ pe pipe fun iwadii lori iṣẹlẹ bẹẹ jẹ igbiyanju lati ṣatilẹyin fun ifẹ awọn kan ti wọn ko fẹran Naijiria.

Onanuga ni igbesẹ naa jẹ iyalẹnu to si tun banilọkan jẹ pe Atiku n fi ẹjọ Aarẹ Naijiria sun Aarẹ Donald Trump nitori erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria.

O ni igbesẹ naa jẹ abuku fun orilẹ ede yii ati pe o fẹ ba Naijiria jẹ loju gbogbo agbaye lati le mu ifẹ inu rẹ ṣẹ.

"Kii ṣe nitori ifẹ awọn ọmọ Naijiria lo ṣe n gbe igbesẹ bikoṣe nitori erongba rẹ lati gba ipo agbara lai fi gbogbo ọna ti erongba naa fi maa waye ṣe.

O fi kun pe ṣaaju eto idibo 2023 ni ọrọ naa ti kọkọ jẹ jade ti ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria si ti dajọ le lori ti idajọ ile ẹjọ ṣi duro digbi.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹnusọ aarẹ ninu atẹjade naa tun sọ pe ti Atiku ba le na owo to le ni miliọnu kan dọla lati fi ṣe iwadii Tinubu, o ni o yẹ ki Atiku naa le sọrọ nipa igbẹjọ rẹ to w ani Amẹrika kan naa.

O fẹsun kan pe Atiku ati iyawo rẹ tẹlẹ ri, Jennifer Douglas wa lara awọn ti iwadii ile aṣofin Amẹrika lọdun 2010 fẹsun kan pe wọn lo awọn ileeṣẹ kan lati fi san owo abẹtẹlẹ ni Amẹrika.

Onanuga ni o yẹ ki Atiku lo ọrọ rẹ lati fi ṣe afọmọ ara rẹ lori ẹsun naa ni.

Ẹwẹ, agbẹnusọ Atiku, Abdulrashid Sharada sọ pe ko ootọ kankan ninu ẹsun ti ileeṣẹ aarẹ fi kan Atiku lori iwadii naa.

Atiku sọ pe ṣiṣe agbedide igbẹjọ naa ṣe Pataki nitori o maa fun Aarẹ Tinubu ni anfaani lati ṣe afọmọ ara rẹ lori ohun to fa igbẹjọ to fi mu u jọwọ awọn ohun ini rẹ kan fun ijọba Amẹrika lori ẹsun to niiṣe pẹlu gbigbe egbogi oloro.

O sọ pe ohun to yẹ kawọn eeyan gboriyin fun ni nitori o maa jẹ kawọn eeyan mọ nipa iru eni to n ṣejọba le wọn lori gan-an ati pe aarẹ ko i tii wẹ ara mọ lori ẹsun naa.

O fi kun pe awọn gbọ pe ileeṣẹ aarẹ ti n gbiyanju lati pa ẹjọ naa mọlẹ ti wọn si ti na owo to to miliọnu mẹwaa dọla lati fi pa ẹjọ naa mọlẹ.

Bi igun mejeeji ṣe n sọ ipo wọn lori ẹsun naa, awọn onwoye ọrọ oṣelu ni Naijiria gbagbọ pe ọrọ naa maa tun wa lara ohun ti awọn eeyan yoo maa jiroro le lori ṣaaju idibo ọdun 2027.

Awọn mii ẹwẹ n fẹ idajọ to maa ṣe afọmọ awọn iwa ibajẹ atawọn iwa ajẹbanu tawọn oloṣelu Naijiria n koju ṣaaju ki wọn to de ipo oṣelu.