You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Adeleke pàṣẹ kí àtúnṣe bẹ̀rẹ̀ lórí afárá tó bẹ̀rẹ̀ sí ń yẹ̀ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n ṣi nílùú Osogbo
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iṣẹ atunṣe lapakan afara Lameco to wa niluu Osogbo lẹyin to bẹrẹ si n yẹ laarin ọsẹ diẹ ti wọn ṣi.
Afara naa ti iye ti wọn ṣe jẹ ₦8.52bn ni Adeleke sọ pe awọn kan lọ mọọmọ ba a jẹ lati tabuku ijọba oun.
Ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2026 yii ni wọn ṣi afara naa ti iwọn rẹ jẹ 672 mita.
Amọ o ṣeni laanu pe ko tii to ọsẹ mẹta pere ti wọn ṣi ti apakan rẹ bẹrẹ si n jin wọnu lẹyin ojo arọrọda kan.
Afara ọhun wa lara akanṣẹ iṣẹ afara ti ijọba Adeleke ya ₦100bn fun, o si jẹ ara eyii ti yoo so awọn ilu bii Osogbo, Ile-Ife, Owode-Ede, ati Ikirun pọ mọ ara wọn.
Lẹyin to bẹrẹ si n jin wọnu ni ijọba ti afara naa pa ti iṣẹ si bẹrẹ lori atunṣe rẹ.
Nigba to n sọrọ lasiko to ṣabẹwo ṣi afara ọhun, gomina naa kan sara si ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ iṣẹ fun bi wọn ṣe tete bẹrẹ iṣẹ atunṣe naa.
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ, Adeleke sọ pe ijọba oun ko jẹ ṣe iṣẹ abuku ati eyii ti ko ni wa fun ọpọ ọdun fun eeyan ipinlẹ naa lailai.
O ni "Mo rọ awọn agbofinro ki wọn mu iṣẹ aabo awọn ohun ini ilu lọkunkundun, ki wọn si ṣawari awọn ti wọn ṣiṣẹ labi yii, ki wọn fi ṣikun ofin mu wọn, ki wọn si ri daju pe wọn foju wina ofin.
"Awọn eeyan ipinlẹ Osun lo ni afara yii, awọn ọmọ Naijiria rere si gbọdọ ri daju pe wọn daabo bo o lọwọ awọn aṣebi to fẹ maa ba a jẹ.
"Ijọba mi ṣetan maa ṣe awọn akanṣẹ iṣẹ to dara lai wo ti awọn ti wọn n gbiyanju lati ba iṣe wa jẹ."
Ọrọ afara naa ti fa gbas-gbos laarin ijọba Osun atawọn ẹgbẹ alatako.
Iṣẹlẹ yii lo n waye ṣaaju eto idibo sipo gomina ti yoo waye lọjọ karundinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 yii.