You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kílódé tí àwọn èèyàn ń fi ohùn ránṣẹ́ sí Gheghe lórí ayélujára?
Ọpọ eeyan lo ti bẹrẹ si n jẹ ọrọ Emmanuel Obruste, ti inagijẹ rẹ n jẹ GheGhe lẹnu bayii lẹyin ti fidio igbeyawo rẹ lu sita.
Gheghe gbajumọ fun awọn ọrọ to maa n sọ lori ayelujra fun awọn ọkunrin lori bi wọn ko sẹ gbọdọ maa na owo wọn fun obinrin.
Ninu ọrọ rẹ, o ni oponu ni ọkunrin to ba n na owo fun obinrin yala nitori ifẹ tabi nnkan mii.
Koda, o tilẹ sọ lasiko igba kan ri pe ki awọn ọkunrin to n tẹle ohun ma ṣe igbeyawo nitori ko si anfani kankan ti igbeyawo n ṣe fun awọn ọkunrin, ayafi obinrin nikan.
Amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti fidio atawọn aworan kan bẹrẹ si n mi igboro titi ninu eyii ti oun ati obinrin kan wa ninu rẹ, to si fara jọ igbeyawo.
Ọpọ eeyan lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ọkunrin naa bayii lẹyin ti wọn ni o dalẹ awọn latari bo ṣe lọ ṣe igbeyawo nigba to n gba awọn nimọran ki awọn ma ṣe igbeyawo.
Nitori ọrọ Gheghe ni mọ ṣe kọ ọrẹbinrin mi silẹ – Carter Efe
Lara awọn to n fẹsun kan Gehgeh ni Carter Efe to sọ pe nitori ọrọ rẹ loun ṣe fopin si ibaṣepọ pẹlu afẹsọna oun ọpọ ọdun.
Carter Efe sọ pe "Ṣe pe Gehgeh le laya lati lọ ṣe igbeyawo lẹyin gbogbo ọrọ to maa n sọ.
"Gheghe lo ki n fi ibaṣepọ mi silẹ. Ibaṣepọ ti mo wa ninu rẹ fun odidi ọdun mejila.
"Oponu ni Gheghe. O ti dalẹ gbogbo wa."
"Mi o sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe igbeyawo"
Ẹwẹ, lẹyin ti aworan oun ati obinrin fa ori ayelujra ya tan lo sọ pe oun ko ni ki ẹnikẹni ma ṣe igbeyawo.
O ni "Ko si asiko ti mo sọ fun eyikeyi ninu yin pe ẹ ko gbọdọ ṣe igbeyawo. Ṣe mo sọ bẹẹ ni? Ti mo ba sọ bẹẹ, ẹ mu fidio ibi ti mo ti so bẹẹ jade.
"Awọn ọmọ Naijiria ko mọ bi oju opo ayelujara ṣe n ṣe n ṣiṣẹ, to ba jẹ pe wọn mọ ni, wọn ko ni toṣi mọ."
Wayi o, awọn kan ti n sọ pe igbayawo naa le jẹ ofege ati awada mii ti yoo tun fi pa owo wọle.