You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn olùgbé Akure pariwo lórí òórùn tó gbalẹ̀ kan, ìjọba bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Awọn olugbe ilu Akure ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo ti ke gbare lori oorun to gbalẹ kan niluu naa.
Lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Họnarebu Jumoke Akindele, kọminu lori oorun naa eyi ti o sọ pe o le ṣakoba fun ilera araalu ati ayika.
Arabinrin Akindele ṣalaye loju opo Facebook rẹ pe oorun ọhun dabi oorun ''sulphur'', ati pe ni oru lawọn olugbe ilu Akure maa n gbọ oorun naa ju.
O wa rọ awọn ajọ ijọba tọrọ kan lati ṣewadii ohun to ṣokunfa nnkan to n run yii ko ma baa ṣakoba fun ilera araalu.
Ọpọ awọn olugbe ilu Akure lawọn naa ti jẹrii si ọrọ ti adari ile igbimọ aṣofin Ondo tẹlẹ sọ nipa oorun to gbalẹ kan l'Akure.
Ọgbẹni Akintunde Tolulope Adeyemi to jẹ ọkan lara awọn olugbe ilu Akure sọ pe oun ati iyawo oun kọkọ ro pe eebi lo n run ninu ile awọn kawọn to mọ pe lati ita ni oorun naa ti n wa.
Oguntunwase Kunle loun naa n gbọ oorun ọhun, o si ke pe ijọba lati wa nnkan ṣe si ọrọ naa ni kiakia.
Olarewaju Temitope Monsurat to n gbe agbegbe Oba-Ile sọ fawọn akọroyin wi pe oorun ọhun lo ji oun loru eyi to si jẹ koun naa ji ọkọ oun silẹ.
Ọgbẹni Adekunle Adedeji sọ pe o ti to ọjọ meloo kan bayii ti oorun naa ti n run kaakiri ilu Akure.
Yeye Babatunde to n gbe lopopona Oda ṣalaye pe lati bii ago mẹwaa alẹ ni oorun naa ti maa n bẹrẹ.
Don Barry King loun ti fọrọ naa to ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo to n ri si ọrọ ayika leti tẹlẹ, amọ, wọn o gbe igbesẹ kankan lori rẹ.
Ọpọ olugbe ilu Akure lo ti wa ke pe ijọba bayii lati ṣawari nnkan to n run, ki wọn si fopin si i.
''Iwadii ti fi han pe oorun yii ko ṣẹyin awọn eeyan kan ti wọn n da idọti lọna aitọ sina odo to n ṣan''
Ẹwẹ, ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo to n ri ọrọ ayika ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ti gbọ nipa oorun sulphur to gbalẹ kan niluu Akure.
Ajọ naa ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe iwadii ti fi han pe oorun yii ko ṣẹyin awọn eeyan kan ti wọn n da idọti lọna aitọ sina odo to n ṣan lati inu ilegbee Ijapo Estate lọ Edo Lodge to fi de agbegbe Fiwasaye lọ sẹyin ilegbee El-Shaddai Residential Estate, Alagbaka, l'Akure.
Ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ayika sọ pe oorun yii le ṣakoba fun ilera araalu ati si ayika, ati pe o tako ofin lori imọtoto nipinlẹ Ondo.
Kọmiṣọna fun ọrọ ayika nipinlẹ Ondo, Dokita Tob Loko, ti wa gbe igbimọ kan dide lati ṣewadii ibi ti oorun naa ti n wa gan an.
Dokita Loko tun paṣẹ fun igbimọ naa lati ṣawari awọn to wa nidi ọrọ naa, ki wọn si ri pe wọn foju wina ofin.
Ijọba ipinlẹ Ondo tun wa fi da araalu loju pe oun ko ni beṣu bẹgba lati daabo awọn olugbe ipinlẹ naa ati ayika wọn.
Kọmiṣọna ni iru oorun bayii ati ṣiṣe idọti kiri lodi sofin, ati pe iwa ọdaran sawọn araalu ni, eyi ti ijọba ko ni foju ire wo.
Nigba ti iwadii n lọ lati ṣawari awọn to wa nidi iṣẹlẹ yii, ijọba ti rọ araalu lati maa foya.
Kọmiṣọna fun ọrọ ayika tun wa rọ araalu lati fi to ijọba leti ti wọn ba kẹẹfin ẹnikẹni to n ṣe idọti si ayika tabi to n ṣe nnkan to lodi sofin lori ọrọ imọtoto.