Kókó nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìjà àkọ́kọ́ tí Anthony Joshua jà lẹ́yìn tí ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní Naijiria

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Abẹṣẹkubiojo Anthony Joshua fi ẹsẹ dara si alatako rẹ, Kristian Prenga, lara ninu ija akọkọ ti o ja lẹyìn tí ijamba ọkọ gbẹmi awọn ọrẹ rẹ ni Naijiria.

Igba meji ọtọọtọ ni Joshua fi idi jalẹ ní ipele akọkọ ija naa, kí o to gbọnra nu ti o si lu Prenga ni alubami.

Ìja náà to waye niluu Jeddah lorilẹede Saudi Arabia lo jẹ ija akọkọ iru rẹ lẹyìn tí àwọn ọrẹ rẹ meji ti won jọ wa sile ọdun, Sina Ghami ati Latif 'Latz' Ayodele ku ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lopopona marose Eko s'ibadan.

Prenga lo kọkọ fun Joshua ni ẹṣẹ ni agbọn ti o si fi idi jalẹ.

Ni ṣe lo dabi ala nigba ti Joshua fidi jalẹ, nitori bi alatako rẹ ṣe jinna si i lagbo awọn akẹṣẹ.

O tun jẹ iyalẹnu tori bi awọn ololufẹ ẹṣẹ kikan ṣe n foju sọna sí ìjà ti yoo waye laarin Tyson Fury ati Joshua.

Amọ, agbo Joshua to tada mẹyin lọ mu agbara wa nigba to bẹrẹ sii ni rọjo ẹṣẹ le Prenga lori ni ipele keji ija ọhun.

Bayii ni ọkan lara ẹṣẹ Joshua la Prenga mọlẹ ti rẹfiri si da ija naa duro ki Prenga maa ba ṣeṣe pupọ ju.

Nigba ti o n sọrọ lori ẹṣẹ to la Prenga mọlẹ naa, Joshua ni "eleyii ju agbara ẹsẹ lọ.

Imisi to ni ṣe pẹlu Latz àti Sina to fi mọ ẹbi wọn lo wa nidii ẹsẹ naa.

O si n ba mi ninu jẹ láti sọ nipa iku awọn ọrẹ mi, o bami lọkàn jẹ gidigidi."

Ahesọ ọrọ ti wa lori ayelujara ṣaaju wi pe Tyson Fury le yọju sibi ija Joshua ati Prenga.

Joshua sọ nípa ija rẹ pẹlu Fury to n bọ pe "mo gba fun Fury pẹlu gbogbo aṣeyọri rẹ lagbo ẹṣẹ kikan.

Amọ, awọn to ba n ja lọwọ bayii ni a maa sọ nípa wọn.

Mo gbagbọ pe awọn eeyan yoo wa wo ija naa."

Joshua ati Fury ti buwọ́lu adehun lati ba ara wọn ja, amọ, wọn ko tii kede ọjọ ati ibi ti ija naa yoo ti waye.

Ju gbogbo rẹ lọ Joshua pada dunnu lọ sile lẹyin to borí ija akọkọ rẹ to ja lẹyìn t'awọn ọrẹ rẹ meji ku ninu ijamba ọkọ ni Naijiria.