You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Mo bí ọmọ ṣùgbọn mi ò dá ọmọ náà mọ̀; Mi ò rántí ohunkóhun mọ́ lẹ́yìn tí mo bí ọmọ mi'
- Author, Outlook
- Role, BBC World Service
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Idile Musulumi ni wọn bi si, o si lo igba ewe rẹ nilẹ Amẹrika ati orilẹede India.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC lori eto Outlook, o ni awọn dokita sọ pe ko sewu nigba to ni oyun rẹ akọkọ lọdun 1999.
Wọn ṣe oniruru ayẹwo, wọn si sọ pe alaafia ni ọmọ inu rẹ wa, ko si si ewu kankan fun ọmọ naa.
O ni "Nigba ti yoo di oṣu keje ti mo ti loyun ni mo bẹrẹ si n ri awọn apẹrẹ kan – mo si ro pe mo ti bẹrẹ n siwin.
"Niṣe ni gbogbo ara mi wu, mo n bi, oju mi si bẹrẹ si n poyi."
Sibẹsibẹ, awọn dokita n sọ fun pe ko si ewu kankan fun nitori o ṣi kere.
Aisan asiko oyun
Samina ati ọkọ rẹ Scott, to jẹ onkọwe bẹrẹ si n ṣewadii lori ayelujara.
Lara awọn ohun ti wọn n ṣewadii rẹ ni ohun to le ṣẹlẹ si obinrin lasiko to ba loyun.
O ni awọn mejeji ka iwe kan ti orukọ rẹ n jẹ 'What to Expect When You're Expecting' ninu eyii ti wọn ti ri aisan 'pre-eclampsia' to ṣalaye apẹrẹ ti oun funra ẹ n ri lasiko naa.
Aisan Pre-eclampsia maa n ṣe awọn obinrin kan ti wọn ba loyun, ori ibi ọmọ lo si ti maa n bẹrẹ.
Aisan naa maa n ṣe ipalara fun ọpọ ẹya ara obnrin, fun awọn kan, o maa n de ọpọlọ wọn pẹlu.
Lara awọn apẹrẹ asisan naa ni ẹjẹ riru, ori fifọ kikankikan, eroja protein ninu itọ ati oju to n riran baibai.
Asiko ti Samina bẹrẹ si n rọbi ni wahala rẹ bẹrẹ.
O ni "Mo bẹrẹ si n jẹrora to pọ, kii ṣe irora irọbi nikan o, ori ati aya mi bẹrẹ si n dun mi, o si da bii pe o fẹ bẹ.
"Dokita to n gbẹbi mi duro si ẹyin awọn nọọsi miran ko ma ba a dahun awọn ibere mi.
Ẹjẹ mi bẹrẹ si n ru soke kọja bo ṣe yẹ, gbogbo igba ti mo ba n ti ọmọ naa jade ni mo n daku ti awọn nọọsi yoo tun ji mi pe ki n gbin.
Nigba to ya, ọpọlọ mi kọṣẹ, aya to n dun mi di nnkan mii."
Lẹyin naa ni Samina ko ranti nnkankan mọ, paapaa awọn irora to n ba finra lasiko naa.
Lẹyin ọjọ marun un to daku lo to pada ji.
Lẹyin to ji tan, o da awọn obi rẹ mọ, o si le sọ ede abinibi wọn, Urdu.
Amọ o ṣeni laanu pe ko ranti ọkọ rẹ mọ, bẹẹ ni ko le sọ ede Gẹẹsi ti ko tun ranti pe oun bimọ.
Awọn dokita to n tọju rẹ ro pe yoo gbadun to ba ri ọmọ rẹ amọ pabo ni igbiyanju wọn ja si.
Lẹyinorẹyin, o pada bẹrẹ si n sọ ede Gẹẹsi diẹdiẹ amọ ko tii ranti ọpọ nnkan ati eeyan mọ.
Samina ni niṣe ni oun wa nilo iranlọwọ awọn to sunmọ oun gẹgẹ bii ọmọ tuntun ti wọn ṣẹṣe bi.
O ni "Niṣe ni mo dabi ọmọ kekere, ẹru n ba mi, mo wa bẹrẹ si n kọ ọpọlọpọ nnkan lakọtun…. Bo tilẹ jẹ pe mo ti pe lọmọ ọgbọn ọdun, niṣe ni mo dabi bii ọmọ mi."
O sọ fun BBC pe asiko ti iya oun ba n tọju ọmọ oun lọwọ loun maa n jowu ti oun yoo si fẹ ki obinrin naa maa tọju lasiko kan naa.
Samina fidi rẹ mulẹ pe oun sọ ọmọ oun di orogun.
Awọn dokita rẹ ni to ba pada sile, yoo ranti ọpọ nnkan amọ niṣe ni ile naa da bii ile alejo loju rẹ.
Lẹyin ọsẹ mẹfa ni ara to balẹ lẹyin to ri aworan igbeyawo oun ati ọkọ rẹ, o bẹrẹ si n ranti diẹdiẹ, ọpọlọ rẹ si bẹrẹ si n pada bọ sipo.
Ọdun marun un lẹyin iṣẹle naa, ara Samina balẹ daadaa, koda o ti kọ iwe nipa iriri rẹ eyii to pe ni 'Madras on Rainy Days.'
Iwe ọhun da lori iriri rẹ ati ibaṣepọ rẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ, Ishmael.
Ni bayii to ku diẹ ko pe ọgbọn ọdun ti iṣẹlẹ naa waye, o wo ẹyin wo, o si n dupẹ lọwọ Eledua.
Lẹyin ọdun mẹwaa to bi Ishmael lo bi ọmọbinrin mii ti gbogbo wọn si wa laye ati alaafia titi di oni yii.