You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹkún sọ níbí ìsìn ìrántí fún olóògbé John Olaleye olùkọ́ Oriire táwọn jàndùkú ajínigbé ṣekúpa
Ẹkun sọ nibi isin iranti oloogbe John Olaleye, ọkan lara awọn olukọ to padanu ẹmi wọn nibi ikọlu awọn janduku ajinigbe to waye ni ile ẹkọ Esinele ati Yawota nijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso.
Lọjọ Abamẹta ti i ṣe ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Keje yii ni eto naa waye ni Ijo onitẹbomi Emmanuel Baptist Church to wa ni agbegbe Isale Afon niluu Ogbomoso.
Eto naa ni won se lati iranti oloogbe Olaleye olukọ imọ isiro ẹniti awọn agbebon sẹkupa nigba ti wọn wa ninu igbo.
Ẹsẹ ko gba ero ni ile ijosin naa bi awọn akẹẹgbẹ oloogbe naa ni ile ẹkọ girama Ahoro Esinele, awọn ọrẹ, ati awọn to n kẹdun darapo mọ idile oloogbe Olaleye lati bu ẹyẹ ikẹyin fun un.
Bi eeyan ba je ori ahun, yoo sun ẹkun nigba ti akobi oloogbe naa, Daniel Olaleye n ka itan igbesi aye baba rẹ, ati awọn ile ẹkọ to ti kawe gboye, ati awọn ibi to ti ṣíṣe ṣaaju ki wọn to gbe lọ si ilu Ahoro Esinele nibi ti o ti sagbako iku ojiji lọwọ awọn agbebon to gbemi rẹ ni akata wọn.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku akọkọ oṣu kẹfa ọdun yii ni awọn agbebon ọhun sẹkupa Ọgbẹni Olaleye, gẹgẹ bi giwa ile ẹkọ girama, Ahoro Esinele, iyẹn, Arabinrin Rachael Alamu ṣe fi idi rẹ mulẹ.
Iku John Olaleye ko din Ọlọrun ku
Ninu iwaasu rẹ, Alufaa ijọ onitẹbomi Emmanuel Baptist Churh, Ẹni-ọwọ Daniel Adewole, ṣalaye wi pe iku oloogbe John Olaleye ko din Ọlọrun ku.
Alufaa Adewole to fi iwe Samueli keji ori Kejila ẹsẹ ìkẹrin din logun si ikarun le logun waasu rọ iyawo oloogbe lati mu ọkan, ko si ṣe itọju ara rẹ ati awọn ọmọ rẹ.
O rọ arabinrin naa lati duro ṣinṣin ninu Ọlọrun, ko si fi igbagbọ sinu Ọlọrun ki o le ni ifọkanbalẹ.
Lara awọn to sọrọ ikẹdun ninu eto naa ṣapejuwe oloogbe gẹgẹ bi ẹni ti o fẹran lati maa pa owe, nigba kugba ti o ba n sọrọ.
Ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ni Oloogbe John Olaleye, iyawo kan ati ọmọ mẹta lo fi saye lọ.
Won ko ti i gbe oku Diakoni John Olaleye wale
BBC News Yoruba ri aridaju rẹ wi pe titi di akoko yii, wọn ko ti i gbe oku oloogbe naa wale.
Saaju ni iyawo oloogbe naa ti ke pe ijọba wi pe ki wọn gbe oku ọkọ oun foun ki ẹbi le sin in.
Ẹ ma gbagbe wi pe olukọ mẹta lọ padanu ẹmi wọn lọwọ awọn afurasi agbebon naa.
Ni kete ti awọn eeyan naa de ahamọ ajinigbe ni wọn bẹ ori Ọgbbẹni Micheal Oyedokun, to jẹ olukọ mii, ti wọn si ka fidio iṣẹlẹ naa silẹ fun gbogbo aye lati ri, ki wọn to gba ẹmi John Olaleye naa pẹlu.