Àlàyé rèé lórí bọ́wọ́ ṣe tẹ afurasí sọ́jà tó ń ta aṣọ ọmọ ogun Naijiria fún áwọn agbésùnmọ̀mí

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ologun Naijiria ti fọwọ ofin mu afurasi ọmogun kan ti wọn fẹsun kan pe o ta nnkan elo ologun to fi mọ aṣọ awọn sọja fawọn agbesunmọmi atawọn ọdaran mii.

Afurasi naa, Mohammed Yusuf pẹlu nọmba 23NA/84/1939 Private to n ṣiṣẹ pẹlu ẹka ileeṣẹ ologun to n ran aṣọ awọn ọmogun niluu Eko ni wọn mu ni nnkan bii ago mẹfa aabọ lopin ọsẹ to kọja lẹyin iṣẹ iwadii kan ti ileeṣẹ ologun ṣe.

Lọjọ kẹtalelogun oṣu Keje yii ni ileeṣẹ ologun kede wi pe awọn n wa Yusuf.

Ni ibudokọ Jidari niluu Maiduguri nipinlẹ Borno lọwọ ti tẹ ẹ nibi to ti fẹ salọ si orilẹede Cameroon.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun, Mohammed Goni, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe Yusuf sa kuro lẹnu iṣẹ rẹ lọjọ keje oṣu Keje yii, o si morile ilu Maiduguri.

Goni sọ pe agbegbe Gomari ni ijọba ibilẹ Jere ni Yusuf lọ sapamọ si niluu Maiduguri.

Ileeṣẹ ologun ni bi ọwọ ṣe tẹ Yusuf n ṣapejuwe aṣeyọri iṣẹ iwadii ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọmogun.

Goni fikun ọrọ rẹ pe eyi tun ni ṣe pẹlu bi ileeṣẹ ologun ṣe n ri wi pe ọmogun to ba tasẹ agẹrẹ foju wina ofin.

Afurasi naa ti wa ni ahamọ bayii, lati ibẹ si ni iwadii kikun yoo ti waye lori rẹ atawọn mii ti wọn ba jọ gbimọ pọ lati ta nnkan elo ologun fawọn agbesunmọmi.

Ikọ Hadin Kai sọ pe ileeṣẹ ologun ko ni foju ire wo ọmogun to ba n gbabọde fawọn agbesunmọmi.

Goni tun sọ pe ileeṣẹ ologun ko ni kaarẹ ninu igbiyanju rẹ lati maa gbogun ti awọn agbesunmọmi.

Ileeṣẹ ologun wa rọ awọn araalu wi pe ki wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọmogun ki alaafia le jọba lawujọ.