You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
America kìlọ̀ fáwọn ọmọ Nàìjíríà tó tún jẹ́ ọmọ America láti má ṣe lo ìwé ìrìnná míràn yàtọ̀ sí ti orílẹ̀èdè náà láti wọlé tábì jáde l'America
Ajọ to n ri si irinajo lọ si orilẹede America lati Naijiria (United States Mission in Nigeria), ti kilọ pe kawọn ọmọ Naijiria to tun jẹ ọmọ orilẹede America ma ṣe lo iwe irinna (passport) miran lati fi rin irinajo lọ si America tabi fi jade kuro nibẹ, bi ko ṣe pe ojulowo iwe irinna ti America ni wọn gbọdọ lo.
Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi lede loju opo X rẹ lọjọ Aiku, ni wọn ti kede pe eyi kan gbogbo ọmọ oniluu l'America pẹlu, titi kan awọn ọmọde to ba ti jẹ ọmọ oniluu meji.
Nibo ni ofin yii sise fun?
Gẹgẹ bi alaye ajọ naa, awọn eeyan ti wọn ba jẹ ọmọ oniluu meji ko ni anfaani lati lo iwe irinna ilẹ okeere wọn lati beere fun irinajo lati ori ayelujara, iyẹn "Electronic System for Travel Authorization" (ESTA).
"A fẹ kawọn ọmọ orilẹede America maa wọle ki wọn si maa jade kuro lorilẹde America pẹlu lilo iwe irinna America. Eyi kan awọn ọmọde ti wọn jẹ ọmọ oniluu meji naa."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.
Wọn kilọ pe ẹka to n bojuto irinajo to si tun n ri si aabo nileeṣẹ naa yoo kọ lati buwọlu irinajo fawọn to ba lo iwe irinna ilẹ okeere wọn.
Bakan naa ni wọn rọ awọn ọmọ ilẹ America to n gbe lorilẹede miran, titi kan awọn to n gbe ni Naijria ninu wọn lati ri I daju pe iwe irinna s'America wọn duro rẹgi ki won too dabaa irinajo.
Wọn ni kawọn arinrinajo ri i daju pe ọjọ ko ti I lọ lori iwe irinajo wọn, o kere tan, ki anfaani oṣu mẹfa ṣi wa lori rẹ ki wọn too gbe igbesẹ ati lo o.