You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ wo ilé ìwòsàn táwọn aláboyún ti ń bímọ sórí ẹní
Awọn eeyan abule Badawa to wa ni ijọba ibilẹ Bodinga nipinlẹ Sokoto ti kepe ijọba lati ṣatunṣe ile iwosan alabọde to wa niluu naa eyi to ti dẹnu kọlẹ.
Ile iwosan alabọde Badawa ti dẹnu kọlẹ lati bi ọdun mẹwaa ti atẹgun ojo ti ba apa kan ile iwosan naa jẹ.
Awọn olugbe ilu naa sọ pe o fẹẹ jẹ wi pe gbogbo ẹka ara ile iwosan naa lo ti dẹnu kọlẹ tan.
Ọkan lara awọn olugbe abule naa sọ pe ''ọpọ yara ni ko ni orule mọ, awọn ogiri si ti lanu, diẹ lara ile iwosan wa yii lo si dara tawọn to n wa itọju le lo.''
Awọn ara abule naa sọ pe lọdun 2009 ni wọn kọ ile iwosan naa, eyi ti wọn fẹ kawọn eeyan Badawa ati agbegbe rẹ maa jẹ anfaani rẹ.
Wọn ni ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo maa n wa si ile iwosan alabọde ọhun loṣooṣu lati gba itọju.
''Ọpọ eeyan lati awọn abule to wa lagbegbe abule Badawa ni wọn maa n wa fun itọju ni ile iwosan yii.''
Awọn olugbe ilu Badawa sọ pe dokita meji pere lo maa n tọju gbogbo eeyan to n wa fun itọju nile iwosan naa.
Wọn ni ori ẹni lawọn ti maa n gba itọju tori ko si bẹẹdi ti wọn le lo nile iwosan naa.
Eyi si ṣakoba fun gbogbo eeyan to fi mọ awọn alaboyun to fẹ bimọ gan an.
Gẹgẹ bi awọn olugbe abule naa ṣe sọ, lọpọ igba lawọn alaboyun maa n bimọ soro ẹni tori ko si bẹẹdi ti wọn le lo.
''Inu ile ibimọ ti ko ni orule mọ ninu ile iwosan abule Badawa ni a ti maa n gbẹbi fawọn to ba fẹ bimọ''
Arabinrin kan ti wọn n pe ni Rabi ẹni to maa n ṣeranwọ fawọn alaboyun to ba fẹ bimọ ni nnkan to buru jai ni ipo ti ile iwosan Badawa naa wa.
Rabi ni fun ọpọ ọdun ni ile iwosan naa ti wa ni ipo ti ko dara ti ijọba ko si ṣe atunṣe rẹ.
''Awọn alaboyun maa n to tẹle ara wọn ni ti wọn ba ti de, a si maa n dawọn lohun ni ọkọọkan.
Inu ile ibimọ ti ko ni orule mọ ninu ile iwosan abule Badawa ni a ti maa n gbẹbi fawọn to ba fẹ bimọ.
Ẹni ni a maa n tẹ silẹ tori ko si ibusun ti wọn le lo,'' Rabi lo sọ bẹẹ.
Rabi ni oun ti ṣeranwọ fun o kere tan alaboyun marun lati bimọ ni ile iwosan alabọde Badawa ki o to wa ni ipo to wa bayii.
Awọn eeyan abule Badawa wa rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Sokoto lati ṣe atunṣe ile iwosan naa ni kiakia.